1 ẸNI ọdun mẹdọgbọn ni Amasiah nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba li ọdun mọkandilọgbọn ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ si ni Jehoaddani ti Jerusalemu.
2 O si ṣe eyi ti o tọ li oju Oluwa, ṣugbọn kì iṣe pẹlu ọkàn pipé.
3 O si ṣe, nigbati a fi idi ijọba na mulẹ fun u, o pa awọn iranṣẹ rẹ̀ ti o pa ọba, baba rẹ̀,
4 Ṣugbọn kò pa awọn ọmọ wọn, ṣugbọn o ṣe gẹgẹ bi a ti kọ ọ ninu ofin ninu iwe Mose, ti Oluwa ti paṣẹ wipe, Awọn baba kì yio kú fun awọn ọmọ, bẹ̃li awọn ọmọ kì yio kú fun awọn baba, ṣugbọn olukuluku ni yio kú nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀.