1 ẸNI ogun ọdun ni Ahasi nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba ọdun mẹrindilogun ni Jerusalemu: on kò si ṣe eyiti o tọ́ li oju Oluwa, gẹgẹ bi Dafidi baba rẹ̀:
2 Nitoriti o rìn li ọ̀na awọn ọba Israeli, o si ṣe ere didà fun Baalimu pẹlu.
3 O si sun turari li àfonifoji ọmọ Hinnomu, o si sun awọn ọmọ rẹ̀ ninu iná bi ohun-irira awọn orilẹ-ède, ti Oluwa ti le jade niwaju awọn ọmọ Israeli.
4 O si rubọ, o si sun turari ni ibi giga wọnni, ati lori òke kekere, ati labẹ gbogbo igi tutu.
5 Nitorina Oluwa Ọlọrun rẹ̀ fi i le ọba Siria lọwọ; nwọn si kọlù u, nwọn si kó ọ̀pọlọpọ ni igbekun lọ ninu wọn, nwọn si mu wọn wá si Damasku. A si fi i le ọba Israeli lọwọ pẹlu, ti o pa a ni ipakupa.