2 O si ṣe eyiti o tọ́ li oju Oluwa, gẹgẹ bi gbogbo eyiti Dafidi, baba rẹ̀, ti ṣe.
3 Li ọdun kini ijọba rẹ̀ li oṣù kini, o ṣí ilẹkun ile Oluwa, o si tun wọn ṣe.
4 O si mu awọn alufa wá ati awọn ọmọ Lefi, o si kó wọn jọ si ita ila-õrun.
5 O si wi fun wọn pe, Ẹ gbọ́ temi, ẹnyin ọmọ Lefi; ẹ yà ara nyin si mimọ́ nisisiyi, ki ẹ si yà ile Oluwa Ọlọrun awọn baba nyin si mimọ́, ki ẹ si kó ohun aimọ́ na jade kuro ni ibi mimọ́.
6 Awọn baba wa sa ti dẹṣẹ, nwọn si ti ṣe ibi li oju Oluwa Ọlọrun wa, nwọn si ti kọ̀ ọ silẹ, nwọn si ti yi oju wọn pada kuro ni ibugbe Oluwa, nwọn si ti pa ẹhin wọn da.
7 Nwọn ti tì ilẹkun iloro na pẹlu, nwọn si ti pa fitila, nwọn kò si sun turari, bẹ̃ni nwọn kò ru ẹbọ sisun ni ibi mimọ́ si Ọlọrun Israeli.
8 Nitorina ibinu Oluwa wà lori Juda ati Jerusalemu, o si fi wọn fun wàhala, ati iyanu ati ẹ̀sin, bi ẹnyin ti fi oju nyin ri.