2 Nitoriti ọba ti gbìmọ ati awọn ijoye rẹ̀, ati gbogbo ijọ-enia ni Jerusalemu, lati pa ajọ irekọja mọ́ li oṣù keji.
3 Nitoriti nwọn kò le pa a mọ́ li akokò na, nitori awọn alufa kò ti iyà ara wọn si mimọ́ to; bẹ̃li awọn enia kò ti ikó ara wọn jọ si Jerusalemu.
4 Ọran na si tọ́ loju ọba ati loju gbogbo ijọ-enia.
5 Bẹ̃ni nwọn fi aṣẹ kan lelẹ, lati kede ká gbogbo Israeli, lati Beer-ṣeba ani titi de Dani, lati wá ipa ajọ irekọja mọ́ si Oluwa Ọlọrun Israeli ni Jerusalemu: nitori nwọn kò pa a mọ́ li ọjọ pupọ gẹgẹ bi a ti kọ ọ.
6 Bẹ̃li awọn onṣẹ ti nsare lọ pẹlu iwe lati ọwọ ọba ati awọn ijoye rẹ̀ si gbogbo Israeli ati Juda; ati gẹgẹ bi aṣẹ ọba, wipe, Ẹnyin ọmọ Israeli, ẹ tun yipada si Oluwa Ọlọrun Abrahamu, Isaaki, ati Israeli, On o si yipada si awọn iyokù ninu nyin, ti o sala kuro lọwọ awọn ọba Assiria.
7 Ki ẹnyin ki o má si ṣe dabi awọn baba nyin, ati bi awọn arakunrin nyin, ti o dẹṣẹ si Oluwa, Ọlọrun awọn baba wọn, nitorina li o ṣe fi wọn fun idahoro, bi ẹnyin ti ri.
8 Njẹ ki ẹnyin ki o máṣe ṣe ọlọrùn lile, bi awọn baba nyin, ṣugbọn ẹ jọwọ ara nyin lọwọ fun Oluwa, ki ẹ si wọ̀ inu ibi-mimọ́ rẹ̀ lọ, ti on ti yà si mimọ́ titi lai: ki ẹ si sin Oluwa, Ọlọrun nyin, ki imuna ibinu rẹ̀ ki o le yipada kuro li ọdọ nyin.