20 Oluwa si gbọ́ ti Hesekiah, o si mu awọn enia na lara dá.
21 Awọn ọmọ Israeli ti a ri ni Jerusalemu fi ayọ̀ nla pa ajọ àkara alaiwu mọ́ li ọjọ meje: awọn ọmọ Lefi, ati awọn alufa yìn Oluwa lojojumọ, nwọn nfi ohun-elo olohùn goro kọrin si Oluwa.
22 Hesekiah sọ̀rọ itunu fun gbogbo awọn ọmọ Lefi, ti o loye ni ìmọ rere Oluwa: ijọ meje ni nwọn fi jẹ àse na, nwọn nru ẹbọ alafia, nwọn si nfi ohùn rara dupẹ fun Oluwa, Ọlọrun awọn baba wọn.
23 Gbogbo ijọ na si gbìmọ lati pa ọjọ meje miran mọ́: nwọn si fi ayọ̀ pa ọjọ meje miran mọ́.
24 Nitori Hesekiah, ọba Juda, ta ijọ enia na li ọrẹ, ẹgbẹrun akọ-malu, ati ẹ̃dẹgbãrun àgutan: ọ̀pọlọpọ ninu awọn alufa si yà ara wọn si mimọ́.
25 Gbogbo ijọ-enia Juda pẹlu awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi, ati gbogbo ijọ-enia ti o ti inu Israeli jade wá, ati awọn àlejo ti o ti ilẹ Israeli jade wá, ati awọn ti ngbe Juda yọ̀.
26 Bẹ̃li ayọ̀ nla si wà ni Jerusalemu: nitori lati ọjọ Solomoni, ọmọ Dafidi, ọba Israeli, iru eyi kò sí ni Jerusalemu.