2. Kro 31:1-6 YCE

1 NJẸ nigbati gbogbo eyi pari, gbogbo Israeli ti a ri nibẹ jade lọ si ilu Juda wọnni, nwọn si fọ́ awọn ere tũtu, nwọn si bẹ́ igbo òriṣa lulẹ, nwọn si bì ibi giga wọnni ati awọn pẹpẹ ṣubu, ninu gbogbo Juda ati Benjamini, ni Efraimu pẹlu ati Manasse, titi nwọn fi pa gbogbo wọn run patapata. Nigbana ni gbogbo awọn ọmọ Israeli yipada, olukuluku si ilẹ-ini rẹ̀ si ilu wọn.

2 Hesekiah si yàn ipa awọn alufa, ati awọn ọmọ Lefi nipa ipa wọn, olukuluku gẹgẹ bi iṣẹ-ìsin rẹ̀, awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi fun ẹbọ sisun, ati fun ẹbọ-alafia lati ṣiṣẹ, ati lati dupẹ, ati lati ma yìn li ẹnu-ọ̀na ibudo Oluwa.

3 Ọba si fi ipin lati inu ini rẹ̀ sapakan fun ẹbọ sisun, fun ẹbọ sisun orowurọ ati alalẹ, ati ẹbọ sisun ọjọjọ isimi, ati fun oṣù titun, ati fun ajọ ti a yàn, bi a ti kọ ọ ninu ofin Oluwa.

4 Pẹlupẹlu o paṣẹ fun awọn enia ti ngbe Jerusalemu lati fi ipin kan fun awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi, ki nwọn ki o le di ofin Oluwa mu ṣinṣin.

5 Bi aṣẹ na ti de ode, awọn ọmọ Israeli mu ọ̀pọlọpọ akọso ọkà ati ọti-waini ati ororo, ati oyin wá, ati ninu gbogbo ibisi oko; ati idamẹwa ohun gbogbo ni nwọn mu wá li ọ̀pọlọpọ.

6 Ati awọn ọmọ Israeli ati Juda, ti ngbe inu ilu Juda wọnni, awọn pẹlu mu idamẹwa malu ati agutan wá ati idamẹwa gbogbo ohun mimọ́ ti a yà si mimọ́ si Oluwa Ọlọrun wọn, nwọn si kó wọn jọ li òkiti òkiti.