5 Bi aṣẹ na ti de ode, awọn ọmọ Israeli mu ọ̀pọlọpọ akọso ọkà ati ọti-waini ati ororo, ati oyin wá, ati ninu gbogbo ibisi oko; ati idamẹwa ohun gbogbo ni nwọn mu wá li ọ̀pọlọpọ.
6 Ati awọn ọmọ Israeli ati Juda, ti ngbe inu ilu Juda wọnni, awọn pẹlu mu idamẹwa malu ati agutan wá ati idamẹwa gbogbo ohun mimọ́ ti a yà si mimọ́ si Oluwa Ọlọrun wọn, nwọn si kó wọn jọ li òkiti òkiti.
7 Li oṣù kẹta, nwọn bẹ̀rẹ si ifi ipilẹ awọn òkiti lelẹ, nwọn si pari rẹ̀ li oṣù keje.
8 Nigbati Hesekiah ati awọn ijoye de, ti nwọn si ri òkiti wọnni, nwọn fi ibukún fun Oluwa, ati Israeli enia rẹ̀.
9 Hesekiah si bère lọdọ awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi niti òkiti wọnni.
10 Asariah, olori alufa ti ile Sadoku, si da a lohùn o si wipe, Lati igba ti awọn enia bẹ̀rẹ si imu ọrẹ wá sinu ile Oluwa, awa ní to lati jẹ, a si kù pupọ silẹ: Oluwa sa ti bukún awọn enia rẹ̀; eyiti o kù ni iṣura nla yi.
11 Nigbana ni Hesekiah paṣẹ lati pèse iyàrá-iṣura ni ile Ọlọrun; nwọn si pèse wọn.