19 Nwọn si sọ̀rọ òdi si Ọlọrun Jerusalemu, bi ẹnipe si awọn oriṣa enia ilẹ aiye, ti iṣe iṣẹ ọwọ enia.
20 Ati nitori eyi ni Hesekiah, ọba, ati Isaiah woli, ọmọ Amosi, gbadura, nwọn si kigbe si ọrun.
21 Oluwa si rán Angeli kan, ẹniti o pa gbogbo awọn alagbara ogun, ati awọn aṣãju, ati awọn balogun ni ibudo ọba Assiria. Bẹ̃li o fi itiju pada si ilẹ on tikararẹ̀. Nigbati o si wá sinu ile oriṣa rẹ̀, awọn ti o ti inu ara rẹ̀ jade si fi idà pa a nibẹ.
22 Bayi li Oluwa gbà Hesekiah ati awọn ti ngbe Jerusalemu lọwọ Sennakeribu ọba Assiria, ati lọwọ gbogbo awọn omiran, o si ṣọ́ wọn ni iha gbogbo.
23 Ọ̀pọlọpọ si mu ẹ̀bun fun Oluwa wá si Jerusalemu, ati ọrẹ fun Hesekiah, ọba Juda: a si gbé e ga loju gbogbo orilẹ-ède lẹhin na.
24 Li ọjọ wọnni, Hesekiah ṣe aisan de oju ikú, o si gbadura si Oluwa; O si da a lohùn, O si fi àmi kan fun u.
25 Ṣugbọn Hesekiah kò si tun pada san gẹgẹ bi ore ti a ṣe fun u: nitoriti ọkàn rẹ̀ gbega: nitorina ni ibinu ṣe wà lori rẹ̀, lori Juda, ati lori Jerusalemu.