18 Ati iyokù iṣe Manasse, ati adura rẹ̀ si Ọlọrun rẹ̀, ati ọ̀rọ awọn ariran ti o ba a sọ̀rọ li orukọ Oluwa Ọlọrun Israeli, kiye si i, o wà ninu iwe ọba Israeli.
19 Adura rẹ̀ na pẹlu, bi Ọlọrun ti gbọ́ ẹ̀bẹ rẹ̀, ati gbogbo ẹ̀ṣẹ rẹ̀, ati irekọja rẹ̀ ati ibi ti o gbe kọ́ ibi giga wọnni ti o si gbé ere-oriṣa kalẹ, ati awọn ere yiyá, ki a to rẹ̀ ẹ silẹ, kiye si i, a kọ wọn sinu iwe itan Hosai.
20 Manasse si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, nwọn si sìn i si ile on tikalarẹ̀: Amoni, ọmọ rẹ̀, si jọba ni ipò rẹ̀.
21 Ẹni ọdun mejidilogun ni Amoni, nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba ọdun meji ni Jerusalemu.
22 O si ṣe eyi ti o buru li oju Oluwa, bi Manasse, baba rẹ̀ ti ṣe, nitori Amoni rubọ si gbogbo awọn ere yiyá, ti Manasse baba rẹ̀ ti ṣe, o si sìn wọn:
23 Kò si rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ niwaju Oluwa bi Manasse, baba rẹ̀, ti rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ; ṣugbọn Amoni dẹṣẹ pupọpupọ.
24 Awọn iranṣẹ rẹ̀ si di rikiṣi si i, nwọn si pa a ni ile rẹ̀.