3 Nitori ti o tun kọ́ ibi giga wọnni ti Hesekiah baba rẹ̀, ti wó lulẹ, o si gbé pẹpẹ wọnni soke fun Baalimu, o si ṣe ere oriṣa, o si mbọ gbogbo ogun ọrun, o si nsìn wọn.
4 O tẹ́ pẹpẹ pẹlu ni ile Oluwa, niti eyiti Oluwa ti sọ pe; Ni Jerusalemu li orukọ mi yio wà lailai.
5 O si tẹ́ pẹpẹ fun gbogbo ogun ọrun li àgbala mejeji ile Oluwa.
6 O si mu ki awọn ọmọ rẹ̀ ki o kọja lãrin iná àfonifoji ọmọ Hinnomu: ati pẹlu o nṣe akiyesi afọṣẹ, o si nlò alupayida, o si nṣe ajẹ́, o si mba okú lò, ati pẹlu oṣó: o ṣe buburu pupọ̀ li oju Oluwa lati mu u binu.
7 O si gbé ere gbigbẹ kalẹ, ere ti o ti yá sinu ile Ọlọrun, niti eyiti Ọlọrun ti sọ fun Dafidi ati Solomoni, ọmọ rẹ̀, pe, Ninu ile yi, ati ni Jerusalemu ti emi ti yàn ninu gbogbo ẹ̀ya Israeli, li emi o fi orukọ mi si lailai:
8 Bẹ̃li emi kì yio ṣi ẹsẹ Israeli mọ kuro ni ilẹ na ti emi ti yàn fun awọn baba nyin; kiki bi nwọn ba ṣe akiyesi lati ṣe gbogbo eyiti emi ti pa li aṣẹ fun wọn, gẹgẹ bi gbogbo ofin ati aṣẹ ati ilana lati ọwọ Mose wá.
9 Bẹ̃ni Manasse mu ki Judah ati awọn ti ngbe Jerusalemu ki o yapa, ati lati ṣe buburu jù awọn orilẹ-ède lọ, awọn ẹniti Oluwa ti parun niwaju awọn ọmọ Israeli.