8 Bẹ̃li emi kì yio ṣi ẹsẹ Israeli mọ kuro ni ilẹ na ti emi ti yàn fun awọn baba nyin; kiki bi nwọn ba ṣe akiyesi lati ṣe gbogbo eyiti emi ti pa li aṣẹ fun wọn, gẹgẹ bi gbogbo ofin ati aṣẹ ati ilana lati ọwọ Mose wá.
9 Bẹ̃ni Manasse mu ki Judah ati awọn ti ngbe Jerusalemu ki o yapa, ati lati ṣe buburu jù awọn orilẹ-ède lọ, awọn ẹniti Oluwa ti parun niwaju awọn ọmọ Israeli.
10 Oluwa si ba Manasse wi ati awọn enia rẹ̀; ṣugbọn nwọn kò kiyesi i.
11 Nitorina li Oluwa mu awọn balogun ogun Assiria wá ba wọn, ti nwọn fi ìwọ mu Manasse, nwọn si de e li ẹ̀wọn, nwọn mu u lọ si Babeli.
12 Nigbati o si wà ninu wahala, o bẹ̀ Oluwa Ọlọrun rẹ̀, o si rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ gidigidi niwaju Ọlọrun awọn baba rẹ̀,
13 O si gbadura si i: Ọlọrun si gbọ́ ẹ̀bẹ rẹ̀, o si tun mu u pada wá si Jerusalemu sinu ijọba rẹ̀. Nigbana ni Manasse mọ̀ pe: Oluwa, On li Ọlọrun.
14 Njẹ lẹhin eyi, o mọ odi kan lẹhin ilu Dafidi, niha ìwọ-õrun Gihoni, li àfonifoji, ani li atiwọ ẹnu-bode ẹja, o si yi Ofeli ka, o si mọ ọ ga soke gidigidi, o si fi balogun sinu gbogbo ilú olodi Juda wọnni.