2. Kro 34:3-9 YCE

3 Nitori li ọdun kẹjọ ijọba rẹ̀, nigbati o si wà li ọdọmọde sibẹ, o bẹ̀rẹ si iwá Ọlọrun Dafidi, baba rẹ̀; ati li ọdun kejila, o bẹ̀rẹ si iwẹ̀ Juda ati Jerusalemu mọ́ kuro ninu ibi giga wọnni, ati ere-oriṣa, ati ere yiyá, ati ere didà.

4 Nwọn si wó pẹpẹ Baalimu lulẹ niwaju rẹ̀; ati awọn ere õrun ti o wà lori wọn li o ké lulẹ; ati awọn ere-oriṣa, ati awọn ere yiyá, ati awọn ere didà, li o fọ tũtu, o sọ wọn di ekuru, o si gbọ̀n ọ sori isa-okú awọn ti o ti nrubọ́ si wọn.

5 O si sun egungun awọn alufa-oriṣa lori pẹpẹ wọn; o si wẹ Juda ati Jerusàlemu mọ́.

6 Bẹ̃li o si ṣe ni ilu Manasse wọnni ati ti Efraimu, ati ti Simeoni, ani titi de Naftali, o tú ile wọn yikakiri.

7 Nigbati o si fọ́ awọn pẹpẹ ati ère-oriṣa dilẹ, ti o si ti gún awọn ere yiyá di ẹ̀tu, ti o si ti ké gbogbo awọn ère-õrun lulẹ ni gbogbo ilẹ Israeli, o pada si Jerusalemu.

8 Njẹ li ọdun kejidilogun ijọba rẹ̀, nigbati o ti wẹ̀ ilẹ na mọ́, ati ile na, o rán Ṣafani, ọmọ Asaliah, ati Maaseiah, olori ilu na, ati Joa, ọmọ Joahasi, akọwe iranti, lati tun ile Oluwa Ọlọrun rẹ̀ ṣe.

9 Nigbati nwọn si de ọdọ Hilkiah, olori alufa, nwọn fi owo na ti a mu wá sinu ile Ọlọrun le e lọwọ, ti awọn ọmọ Lefi, ti o ntọju ilẹkun, ti kójọ lati ọwọ Manasse ati Efraimu, ati lati ọdọ gbogbo awọn iyokù Israeli, ati lati gbogbo Juda ati Benjamini: nwọn si pada si Jerusalemu.