1 JOSIAH si pa irekọja kan mọ́ si Oluwa ni Jerusalemu: nwọn si pa ẹran irekọja na li ọjọ kẹrinla oṣù kini.
2 O si yàn awọn alufa si iṣẹ wọn, o si gbà wọn ni iyanju si ìsin ile Oluwa.
3 O si wi fun awọn ọmọ Lefi ti nkọ́ gbogbo Israeli, ti iṣe mimọ́ si Oluwa pe, Ẹ gbé apoti-ẹri mimọ́ nì lọ sinu ile na ti Solomoni, ọmọ Dafidi, ọba Israeli, ti kọ́; kì yio jẹ ẹrù li ejika mọ́: ẹ sìn Oluwa Ọlọrun nyin nisisiyi, ati Israeli, awọn enia rẹ̀;
4 Ẹ si mura nipa ile awọn baba nyin, li ẹsẹsẹ nyin, gẹgẹ bi iwe Dafidi, ọba Israeli, ati gẹgẹ bi iwe Solomoni, ọmọ rẹ̀.