15 Awọn akọrin, awọn ọmọ Asafu duro ni ipò wọn, gẹgẹ bi ofin Dafidi, ati ti Asafu, ati ti Hemani, ati ti Jedutuni, ariran ọba; awọn adèna si duro ni olukuluku ẹnu-ọ̀na; nwọn kò gbọdọ lọ kuro li ọ̀na-iṣẹ wọn, nitoriti awọn arakunrin wọn, awọn ọmọ Lefi, ti mura silẹ dè wọn.
16 Bẹ̃ni a si mura gbogbo ìsin Oluwa li ọjọ kanna, lati pa irekọja mọ́, ati lati ru ẹbọ sisun lori pẹpẹ Oluwa, gẹgẹ bi ofin Josiah, ọba.
17 Ati awọn ọmọ Israeli ti a ri nibẹ, pa irekọja na mọ́ li akoko na, ati ajọ aiwukara li ọjọ meje.
18 Kò si si irekọja kan ti o dabi rẹ̀ ti a ṣe ni Israeli lati igba ọjọ Samueli woli; bẹ̃ni gbogbo awọn ọba Israeli kò pa iru irekọja bẹ̃ mọ́, bi eyi ti Josiah ṣe, ati awọn alufa, ati awọn ọmọ Lefi, ati gbogbo Juda ati Israeli ti a ri nibẹ, ati awọn ti ngbe Jerusalemu.
19 Li ọdun kejidilogun ijọba Josiah li a pa irekọja yi mọ́.
20 Lẹhin gbogbo eyi, ti Josiah ti tun ile na ṣe tan, Neko, ọba Egipti, gòke wá, si Karkemiṣi lẹba odò Euferate: Josiah si jade tọ̀ ọ.
21 Ṣugbọn o rán ikọ̀ si i, wipe, Kini ṣe temi tirẹ, iwọ ọba Juda? Emi kò tọ̀ ọ wá loni, bikòṣe si ile ti mo ba ni ijà: Ọlọrun sa pa aṣẹ fun mi lati yara: kuro lọdọ Ọlọrun, ẹniti o wà pẹlu mi, ki on má ba pa ọ run.