19 Li ọdun kejidilogun ijọba Josiah li a pa irekọja yi mọ́.
20 Lẹhin gbogbo eyi, ti Josiah ti tun ile na ṣe tan, Neko, ọba Egipti, gòke wá, si Karkemiṣi lẹba odò Euferate: Josiah si jade tọ̀ ọ.
21 Ṣugbọn o rán ikọ̀ si i, wipe, Kini ṣe temi tirẹ, iwọ ọba Juda? Emi kò tọ̀ ọ wá loni, bikòṣe si ile ti mo ba ni ijà: Ọlọrun sa pa aṣẹ fun mi lati yara: kuro lọdọ Ọlọrun, ẹniti o wà pẹlu mi, ki on má ba pa ọ run.
22 Ṣugbọn Josiah kò yi oju rẹ̀ pada kuro lọdọ rẹ̀, ṣugbọn o pa aṣọ ara rẹ dà, ki o le ba a jà, kò si fi eti si ọ̀rọ Neko lati ẹnu Ọlọrun wá, o si wá ijagun li àfonifoji Megiddo.
23 Awọn tafatafa si ta Josiah, ọba: ọba si wi fun awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Ẹ gbé mi kuro; nitoriti mo gbà ọgbẹ gidigidi.
24 Nitorina awọn iranṣẹ rẹ̀ gbé e kuro ninu kẹkẹ́ na, nwọn si fi i sinu kẹkẹ́ rẹ̀ keji; nwọn si mu u wá si Jerusalemu, o si kú, a si sìn i ninu ọkan ninu awọn iboji awọn baba rẹ̀. Gbogbo Juda ati Jerusalemu si ṣọ̀fọ Josiah.
25 Jeremiah si pohùn rere ẹkún fun Josiah, ati gbogbo awọn akọrin ọkunrin, ati awọn akọrin obinrin, si nsọ ti Josiah ninu orin-ẹkún wọn titi di oni yi, nwọn si sọ wọn di àṣa kan ni Israeli; si kiyesi i, a kọ wọn ninu awọn orin-ẹkún.