24 Nitorina awọn iranṣẹ rẹ̀ gbé e kuro ninu kẹkẹ́ na, nwọn si fi i sinu kẹkẹ́ rẹ̀ keji; nwọn si mu u wá si Jerusalemu, o si kú, a si sìn i ninu ọkan ninu awọn iboji awọn baba rẹ̀. Gbogbo Juda ati Jerusalemu si ṣọ̀fọ Josiah.
25 Jeremiah si pohùn rere ẹkún fun Josiah, ati gbogbo awọn akọrin ọkunrin, ati awọn akọrin obinrin, si nsọ ti Josiah ninu orin-ẹkún wọn titi di oni yi, nwọn si sọ wọn di àṣa kan ni Israeli; si kiyesi i, a kọ wọn ninu awọn orin-ẹkún.
26 Ati iyokú iṣe Josiah, ati ìwa rere rẹ̀, gẹgẹ bi eyiti a ti kọ ninu ofin Oluwa,
27 Ati iṣe rẹ̀, ti iṣaju ati ti ikẹhin, kiyesi i, a kọ wọn sinu iwe awọn ọba Israeli ati Judah.