2. Kro 35:3-9 YCE

3 O si wi fun awọn ọmọ Lefi ti nkọ́ gbogbo Israeli, ti iṣe mimọ́ si Oluwa pe, Ẹ gbé apoti-ẹri mimọ́ nì lọ sinu ile na ti Solomoni, ọmọ Dafidi, ọba Israeli, ti kọ́; kì yio jẹ ẹrù li ejika mọ́: ẹ sìn Oluwa Ọlọrun nyin nisisiyi, ati Israeli, awọn enia rẹ̀;

4 Ẹ si mura nipa ile awọn baba nyin, li ẹsẹsẹ nyin, gẹgẹ bi iwe Dafidi, ọba Israeli, ati gẹgẹ bi iwe Solomoni, ọmọ rẹ̀.

5 Ẹ si duro ni ibi mimọ́ na, gẹgẹ bi ipin idile awọn baba arakunrin nyin, awọn enia na, ati bi ipin idile awọn ọmọ Lefi.

6 Bẹ̃ni ki ẹ pa ẹran irekọja na, ki ẹ si yà ara nyin si mimọ́, ki ẹ si mura fun awọn arakunrin nyin, ki nwọn ki o le mã ṣe gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa nipa ọwọ Mose.

7 Josiah si fun awọn enia na, ni ọdọ-agutan ati ọmọ ewurẹ, lati inu agbo-ẹran, gbogbo rẹ̀ fun ẹbọ irekọja na, fun gbogbo awọn ti o wà nibẹ, iye rẹ̀ ẹgbã mẹdogun, ati ẹgbẹdogun akọmalu: lati inu ini ọba ni wọnyi.

8 Awọn ijoye rẹ̀ si fi tinutinu ta awọn enia li ọrẹ, fun awọn alufa, ati fun awọn ọmọ Lefi: Hilkiah ati Sekariah ati Jehieli, awọn olori ile Ọlọrun, si fun awọn alufa fun ẹbọ irekọja na ni ẹgbẹtala ẹran-ọ̀sin kekeke, ati ọ̃dunrun malu.

9 Koniah ati Ṣemaiah ati Netaneeli, awọn arakunrin rẹ̀, ati Hasabiah ati Jehieli ati Josabadi, olori awọn ọmọ Lefi, si fun awọn ọmọ Lefi fun ẹbọ irekọja na ni ẹgbẹdọgbọn ọdọ-agutan, ati ẹ̃dẹgbẹta malu.