11 Ẹni ọdun mọkanlelogun ni Sedekiah, nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba ọdun mọkanla ni Jerusalemu.
12 O si ṣe eyi ti o buru li oju Oluwa Ọlọrun rẹ̀, kò si rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ niwaju Jeremiah, woli, ti o sọ̀rọ lati ẹnu Oluwa wá.
13 On pẹlu si ṣọ̀tẹ si Nebukadnessari ọba, ẹniti o ti mu u fi Ọlọrun bura; ṣugbọn o wà ọrùn rẹ̀ kì, o si mu aiya rẹ̀ le lati má yipada si Oluwa Ọlọrun Israeli.
14 Pẹlupẹlu, gbogbo awọn olori awọn alufa ati awọn enia dẹṣẹ gidigidi bi gbogbo irira awọn orilẹ-ède, nwọn si sọ ile Oluwa di ẽri, ti on ti yà si mimọ́ ni Jerusalemu.
15 Oluwa Ọlọrun awọn baba wọn si ranṣẹ si wọn lati ọwọ awọn onṣẹ rẹ̀, o ndide ni kùtukutu o si nranṣẹ, nitori ti o ni iyọ́nu si awọn enia rẹ̀, ati si ibugbe rẹ̀.
16 Ṣugbọn nwọn fi awọn onṣẹ Ọlọrun ṣe ẹlẹya, nwọn si kẹgan ọ̀rọ rẹ̀, nwọn si fi awọn woli rẹ̀ ṣẹsin, titi ibinu Oluwa fi ru si awọn enia rẹ̀, ti kò fi si atunṣe.
17 Nitorina li o ṣe mu ọba awọn ara Kaldea wá ba wọn, ẹniti o fi idà pa awọn ọdọmọkunrin wọn ni ile ibi-mimọ́ wọn, kò si ni iyọ́nu si ọdọmọkunrin tabi wundia, arugbo, tabi ẹniti o bà fun ogbó: on fi gbogbo wọn le e li ọwọ.