18 Ati gbogbo ohun-elo ile Ọlọrun, nla ati kekere, ati iṣura ile Oluwa ati iṣura ọba, ati ti awọn ijoye rẹ̀; gbogbo wọn li o mu wá si Babeli.
19 Nwọn si kun ile Ọlọrun, nwọn si wó odi Jerusalemu palẹ, nwọn si fi iná sun ãfin rẹ̀, nwọn si fọ́ gbogbo ohun-elo daradara rẹ̀ tũtu.
20 Awọn ti o ṣikù lọwọ idà li o kó lọ si Babeli; nibiti nwọn jẹ́ iranṣẹ fun u, ati fun awọn ọmọ rẹ̀ titi di ijọba awọn ara Persia:
21 Lati mu ọ̀rọ Oluwa ṣẹ lati ẹnu Jeremiah wá, titi ilẹ na yio fi san ọdun isimi rẹ̀; ani ni gbogbo ọjọ idahoro on nṣe isimi titi ãdọrin ọdun yio fi pé.
22 Li ọdun kini Kirusi, ọba Persia, ki ọ̀rọ Oluwa lati ẹnu Jeremiah wá ki o le ṣẹ, Oluwa ru ẹmi Kirusi, ọba Persia, soke, ti o si ṣe ikede ni gbogbo ijọba rẹ̀, o si kọ iwe pẹlu, wipe,
23 Bayi ni Kirusi, ọba Persia, wi pe, Gbogbo ijọba aiye li Oluwa Ọlọrun fi fun mi, o si ti paṣẹ fun mi lati kọ́ ile kan fun on ni Jerusalemu, ti mbẹ ni Juda. Tani ninu nyin ninu gbogbo awọn enia rẹ̀? Oluwa Ọlọrun rẹ̀ ki o pẹlu rẹ̀, ki o si gòke lọ.