5 Ẹni ọdun mẹdọgbọn ni Jehoiakimu, nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba ọdun mọkanla ni Jerusalemu; o si ṣe eyi ti o buru li oju Oluwa Ọlọrun rẹ̀,
6 Nebukadnessari, ọba Babeli, gòke wá, o si dè e ni ẹ̀won, lati mu u lọ si Babeli.
7 Nebukadnessari kó ninu ohun-elo ile Oluwa lọ si Babeli pẹlu, o si fi wọn sinu ãfin rẹ̀ ni Babeli.
8 Ati iyokù iṣe Jehoiakimu ati awọn ohun-irira rẹ̀ ti o ti ṣe, ti a si ri ninu rẹ̀, kiyesi i, a kọ wọn sinu iwe awọn ọba Israeli ati Juda: Jehoiakini, ọmọ rẹ̀, si jọba ni ipò rẹ̀.
9 Ẹni ọdun mejidilogun ni Jehoiakini nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba oṣù mẹta ati ijọ mẹwa ni Jerusalemu: o si ṣe eyiti o buru li oju Oluwa.
10 Ati li amọdun, Nebukadnessari ranṣẹ, a si mu u wá si Babeli, pẹlu ohun-elo daradara ile Oluwa, o si fi Sedekiah, arakunrin rẹ̀, jọba lori Juda ati Jerusalemu.
11 Ẹni ọdun mọkanlelogun ni Sedekiah, nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba ọdun mọkanla ni Jerusalemu.