10 O si fi agbada na si apa ọtún igun ile ila-õrun, si idojukọ gusu.
11 Huramu si ṣe ikoko, ati ọkọ́ ati ọpọ́n. Huramu si pari iṣẹ na ti o ni iṣe fun Solomoni ọba ni ile Ọlọrun;
12 Ọwọ̀n meji ati ọta, ati ọpọ́n ti o wà li ori ọwọ̀n mejeji na, ati iṣẹ ẹ̀wọn meji lati bo ọta meji ti ọpọ́n na, ti o wà li ori awọn ọwọ̀n na;
13 Ati irinwo pomegranate li ara iṣẹ ẹ̀wọn meji na, ẹsẹ meji pomegranate li ara iṣẹ ẹ̀wọn kan, lati bo ọta meji na ti ọpọ́n ti o wà lori awọn ọwọ̀n na.
14 O si ṣe ijoko, o si ṣe agbada li ori awọn ijoko na.
15 Agbada nla kan, ati malu mejila labẹ rẹ̀.
16 Ati ikoko ati ọkọ́, ati kọkọrọ-ẹran, ati gbogbo ohun-elo ni Huramu-Abi fi idẹ didan ṣe fun Solomoni ọba, fun ile Oluwa.