16 Ati ikoko ati ọkọ́, ati kọkọrọ-ẹran, ati gbogbo ohun-elo ni Huramu-Abi fi idẹ didan ṣe fun Solomoni ọba, fun ile Oluwa.
17 Ni pẹtẹlẹ Jordani ni ọba dà wọn, ni ilẹ amọ̀ li agbedemeji Sukkoti ati Seredata.
18 Bayi ni Solomoni ṣe gbogbo ohun-elo wọnyi li ọ̀pọlọpọ: nitori ti a kò le mọ̀ ìwọn idẹ na.
19 Solomoni si ṣe gbogbo ohun-elo ti iṣe ti ile Ọlọrun, pẹpẹ wura pẹlu, ati awọn tabili lori eyi ti akara ifihan wà;
20 Ọpa-fitila pẹlu ati fitila wọn, ki nwọn ki o ma jo gẹgẹ bi aṣẹ niwaju ibi-mimọ́-jùlọ, jẹ wura daradara.
21 Ati itanna, ati fitila ati ẹ̀mu li o fi wura ṣe; gbogbo eyi ni wura daradara;
22 Ati alumagaji fitila, ati awo-koto, ati ṣibi ati awo-koto turari, wura daradara ni: ati ọ̀na iwọle, awẹ ilẹkun rẹ̀ ti inu lọhun fun ibi-mimọ́-jùlọ, ati awọn ilẹkun fun ile na, ani tempili, wura ni.