6 Awọn alufa duro lẹnu iṣẹ wọn; awọn ọmọ Lefi pẹlu ohun-ọnà orin Oluwa, ti Dafidi ọba ti ṣe lati yìn Oluwa, nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai, nigbati Dafidi nkọrin iyìn nipa ọwọ wọn; awọn alufa si fùn ipè niwaju wọn, gbogbo Israeli si dide duro.
7 Solomoni si yà arin agbala na si mimọ́ ti mbẹ niwaju ile Oluwa: nitori nibẹ li o ru ẹbọ ọrẹ sisun, ati ọra ẹbọ alafia, nitori pẹpẹ idẹ ti Solomoni ti ṣe kò le gbà ọrẹ sisun, ati ọrẹ onjẹ ati ọ̀ra na.
8 Li akokò na pẹlu Solomoni se àse na ni ijọ meje, ati gbogbo Israeli pẹlu rẹ̀, ijọ enia nlanla, lati ìwọ Hamati titi de odò Egipti.
9 Ati li ọjọ kẹjọ nwọn ṣe apejọ mimọ́; nitori ti nwọn ṣe ìyasi-mimọ́ pẹpẹ na li ọjọ meje, ati àse na, ọjọ meje.
10 Ati li ọjọ kẹtalelogun oṣù keje, o rán awọn enia pada lọ sinu agọ wọn, pẹlu ayọ̀ ati inudidùn nitori ore-ọfẹ ti Oluwa ti fi hàn fun Dafidi, ati fun Solomoni, ati fun Israeli, enia rẹ̀.
11 Solomoni si pari ile Oluwa, ati ile ọba, ati gbogbo ohun ti o wá si ọkàn Solomoni lati ṣe ninu ile Oluwa, ati ninu ile on tikararẹ̀, o si ṣe e jalẹ.
12 Oluwa si fi ara hàn Solomoni li oru, o si wi fun u pe, Emi ti gbọ́ adura rẹ, emi si ti yàn ihinyi fun ara mi, fun ile ẹbọ.