1 NIGBATI ayaba Ṣeba gbọ́ òkiki Solomoni, o wá lati fi àlọ dan Solomoni wò ni Jerusalemu, pẹlu ẹgbẹ́ nlanla, ati ibakasiẹ ti o ru turari, ati wura li ọ̀pọlọpọ ati okuta iyebiye; nigbati o si de ọdọ Solomoni, o ba a sọ ohun gbogbo ti o wà li ọkàn rẹ̀.
2 Solomoni si dahùn gbogbo ibère rẹ̀: kò si si ohun kan ti o pamọ fun Solomoni ti kò sọ fun u,
3 Nigbati ayaba Ṣeba si ti ri ọgbọ́n Solomoni, ati ile ti o ti kọ́,
4 Ati onjẹ tabili rẹ̀, ati ijoko awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀, ati iduro awọn iranṣẹ rẹ̀, ati aṣọ-wiwọ̀ wọn; ati awọn agbọti rẹ̀ pẹlu aṣọ-wiwọ̀ wọn, ati àtẹgun ti o mba gòke lọ si ile Oluwa; kò si kù agbara kan ninu rẹ̀ mọ.