13 Njẹ nisisiyi ìwọn wura ti o de fun Solomoni li ọdun kan ni ọtalelẹgbẹta o le mẹfa talenti wura.
14 Laika eyiti awọn oniṣowo ati awọn èro mu wá. Ati awọn ọba Arabia, ati awọn bãlẹ ilẹ na nmu wura ati fadakà tọ̀ Solomoni wá.
15 Solomoni ọba si ṣe igba asà wura lilù: asà kan gba ẹgbẹta ṣekeli wura lilù.
16 Ọdunrun apata wura lilù li o si ṣe; apata kan gbà ọ̃dunrun ṣekeli wura: ọba si fi wọn sinu ile igbo Lebanoni.
17 Ọba si ṣe itẹ́ ehin-erin nla kan, o si fi wura daradara bò o.
18 Àtẹgun mẹfa ni itẹ́ na ni, pẹlu apoti-itisẹ wura kan, ti a dè mọ itẹ́ na, ati irọpa ni iha mejeji ibi ijoko na, kiniun meji si duro lẹba awọn irọpa na.
19 Kiniun mejila si duro lori atẹgun mẹfẹfa na, ni iha ekini ati ni iha ekeji. A kò ṣe iru rẹ̀ ri ni gbogbo ijọba.