6 Ẹ gbé ojú nyin soke si awọn ọrun, ki ẹ si wò aiye nisalẹ: nitori awọn ọrun yio fẹ́ lọ bi ẹ̃fin, aiye o si di ogbó bi ẹwù, awọn ti ngbe inu rẹ̀ yio si kú bakanna: ṣugbọn igbala mi o wà titi lai, ododo mi kì yio si parẹ́.
7 Gbọ́ ti emi, ẹnyin ti o mọ̀ ododo, enia ninu aiya ẹniti ofin mi mbẹ; ẹ máṣe bẹ̀ru ẹgàn awọn enia, ẹ má si ṣe foyà ẹsín wọn.
8 Nitori kòkoro yio jẹ wọn bi ẹ̀wu, idin yio si jẹ wọn bi irun agutan: ṣugbọn ododo mi yio wà titi lai, ati igbala mi lati iran de iran.
9 Ji, ji, gbe agbara wọ̀, Iwọ apa Oluwa; ji, bi li ọjọ igbãni, ni iran atijọ. Iwọ kọ́ ha ke Rahabu, ti o si ṣá Dragoni li ọgbẹ́?
10 Iwọ kọ́ ha gbẹ okun, omi ibu nla wọnni? ti o ti sọ ibú okun di ọ̀na fun awọn ẹni ìrapada lati gbà kọja?
11 Nitorina awọn ẹni-ìrapada Oluwa yio pada, nwọn o si wá si Sioni ti awọn ti orin; ayọ̀ ainipẹkun yio si wà li ori wọn: nwọn o ri inudidùn ati ayọ̀ gbà; ikãnu ati ọ̀fọ yio fò lọ.
12 Emi, ani emi ni ẹniti ntù nyin ninu: tani iwọ, ti iwọ o fi bẹ̀ru enia ti yio kú, ati ọmọ enia ti a ṣe bi koriko.