1 KỌRIN, iwọ àgan, ti kò bi ri; bú si orin, si ké rara, iwọ ti kò rọbi ri; nitori awọn ọmọ ẹni-alahoro pọ̀ ju awọn ọmọ ẹniti a gbe ni iyawo: li Oluwa wi.
2 Sọ ibi agọ rẹ di gbigbõro, si jẹ ki wọn nà aṣọ tita ibugbe rẹ̀ jade: máṣe dási, sọ okùn rẹ di gigùn, ki o si mu ẽkàn rẹ le.
3 Nitori iwọ o ya si apa ọtún ati si apa osì, iru-ọmọ rẹ yio si jogun awọn keferi: nwọn o si mu ki awọn ilu ahoro wọnni di ibi gbigbe.
4 Má bẹ̀ru, nitori oju kì yio tì ọ: bẹ̃ni ki o máṣe dãmu; nitori a ki yio doju tì ọ; nitori iwọ o gbagbe itìju igbà ewe rẹ, iwọ kì yio sì ranti ẹ̀gan iwà-opo rẹ mọ.
5 Nitori Ẹlẹda rẹ li ọkọ rẹ; Oluwa awọn ọmọ-ogun li orukọ rẹ̀; ati Olurapada rẹ Ẹni-Mimọ Israeli; Ọlọrun agbaiye li a o ma pè e.
6 Nitori Oluwa ti pè ọ bi obinrin ti a kọ̀ silẹ, ti a si bà ni inu jẹ, ati bi aya igba ewe nigbati a ti kọ̀ ọ, li Ọlọrun rẹ wi.