6 Gbogbo wa si dabi ohun aimọ́, gbogbo ododo wa si dabi akisa ẹlẹgbin; gbogbo wa si rẹ̀ bi ewe; aiṣedede wa si mu wa kuro bi afẹfẹ.
7 Kò si ẹniti npè orukọ rẹ, ti o si rú ara rẹ̀ soke lati di ọ mu: nitori iwọ ti pa oju rẹ mọ kuro lara wa, iwọ si ti run wa, nitori aiṣedede wa.
8 Ṣugbọn nisisiyi, Oluwa, iwọ ni baba wa; awa ni amọ̀, iwọ si ni ọ̀mọ; gbogbo wa si ni iṣẹ ọwọ́ rẹ.
9 Máṣe binu kọja àla, Oluwa, ki o má si ranti aiṣedede wa titilai: kiyesi i, wò, awa bẹ̀ ọ, enia rẹ ni gbogbo wa iṣe.
10 Awọn ilu mimọ́ rẹ di aginju, Sioni dí aginju, Jerusalemu di ahoro.
11 Ile wa mimọ́ ati ologo, nibiti awọn baba wa ti nyìn ọ, li a fi iná kun: gbogbo ohun ãyo wa si ti run.
12 Iwọ o ha da ara rẹ duro nitori nkan wọnyi, Oluwa? iwọ o ha dakẹ, ki o si pọn wa loju kọja àla?