19 Bi ẹniti o duro ninu ododo ti ini ìye, bẹ̃ni ẹniti nlepa ibi, o nle e si ikú ara rẹ̀.
20 Awọn ti iṣe alarekereke aiya, irira ni loju Oluwa; ṣugbọn inu rẹ̀ dùn si awọn aduroṣinṣin:
21 Bi a tilẹ fi ọwọ so ọwọ, enia buburu kì yio lọ laijiya, ṣugbọn iru-ọmọ olododo li a o gbàla.
22 Bi oruka wura ni imu ẹlẹdẹ bẹ̃ni arẹwà obinrin ti kò moye.
23 Kiki rere ni ifẹ inu awọn olododo; ṣugbọn ibinu ni ireti awọn enia buburu.
24 Ẹnikan wà ti ntuka, sibẹ o mbi si i, ẹnikan si wà ti nhawọ jù bi o ti yẹ lọ, ṣugbọn kiki si aini ni.
25 Ọkàn iṣore li a o mu sànra; ẹniti o mbomirin ni, ontikararẹ̀ li a o si bomirin pẹlu.