1 Sámúẹ́lì 11:4-10 BMY

4 Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ náà sì wá sí Gíbíà tí ó jẹ́ ìlú Ṣọ́ọ̀lù, wọ́n sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún àwọn ènìyàn, gbogbo wọn gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sì sunkún.

5 Nígbà náà gan an ni Ṣọ́ọ̀lù padà wá láti pápá, pẹ̀lú màlúù rẹ̀, ó sì béèrè pé, “kín ni ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ènìyàn? Èéṣe tí wọ́n fi ń sunkún?” Nígbà náà ni wọ́n tún sọ fún wọn ọ̀rọ̀ àwọn ọkùnrin Jábésì.

6 Nígbà tí Ṣọ́ọ̀lù sì gbọ́ ọ̀rọ̀ wọn, ẹ̀mí Ọlọ́run sì bà lé e pẹ̀lú agbára, inú rẹ̀ sì ru sókè.

7 Ó sì mú màlúù méjì, ó gé wọn sí wẹ́wẹ́, ó sì rán ẹyọyọ sí gbogbo Ísírẹ́lì nípa ọwọ́ àwọn ìránṣẹ́ náà, ó ní i ẹ kéde pé, “Èyí ni a ó ṣe sí màlúù ẹnikẹ́ni tí kò bá tọ Ṣọ́ọ̀lù àti Sámúẹ́lì lẹ́yìn.” Nígbà náà ni ìbẹ̀rù Olúwa sì mú àwọn ènìyàn, wọ́n sì jáde bí ènìyàn kan ṣoṣo.

8 Nígbà tí Ṣọ́ọ̀lù sì kó wọn jọ ní Bésékì, àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì tí a kà jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀dógún. (300,000) àwọn ọkùnrin Júdà sì jẹ́ ẹgbàá mẹ́ẹ̀dógún (30,000).

9 Wọ́n sì sọ fún àwọn ìránṣẹ́ tí ó wá pé, “Sọ fún àwọn ọkùnrin Jabesi-Gílíádì pé, ní àkókò tí oòrùn bá mú lọ́la, àwa yóò gbà yín sílẹ̀.” Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ náà lọ tí wọ́n sì sọ èyí fún àwọn ọkùnrin Jábésì, inú wọn sì dùn.

10 Wọ́n sọ fún àwọn ará Ámónì pé, “Àwa yóò fi ara wa fún un yín ní ọ̀la, kí ẹ̀yin kí ó ṣe gbogbo èyí tí ó tọ́ lójú yín sí wa.”