1 Sámúẹ́lì sì wí fún gbogbo Ísírẹ́lì pé, “Èmi tí gbọ́ gbogbo ohun tí ẹ sọ fún mi, èmi sì ti yan ọba fún un yín.
2 Nísinsìn yìí ẹ ti ní ọba bí olórí yín. Bí ó ṣe tèmi, èmi ti di arúgbó, mo sì ti hewú, àwọn ọmọ mi sì ń bẹ níhìn yìí pẹ̀lú yín. Èmi ti ń ṣe olórí yín láti ìgbà èwe mi wá títí di òní yìí.
3 Èmi dúró níhìn yìí, ẹ jẹ́rìí sí mi níwájú Olúwa àti níwájú ẹni àmì òróró rẹ̀. Màlúù ta ni mo gbà rí? Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ta ni mo gbà rí? Ta ni mo rẹ́ jẹ rí? Ọwọ́ ta ni mo ti gba owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ kan rí láti fi ti ara mi lójú? Bí mo bá ti ṣe ìkankan nínú ohun wọ̀nyí, èmi yóò sì san án padà fún un yín.”
4 Wọ́n sì dáhùn wí pé, “Ìwọ kò rẹ́ wa jẹ tàbí pọ́n wa lójú rí, ìwọ kò sì gba ohunkóhun lọ́wọ́ ẹnìkankan.”
5 Samúẹ́lì sì wí fún wọn pé, “Olúwa ni ẹlẹ́rìí sí i yín, àti ẹni àmì òróró rẹ̀ ni ẹlẹ́rìí lónìí pé, ẹ̀yin kò rí ohunkóhun lọ́wọ́ mi.”Wọ́n sì sọ wí pé, “Òun ni ẹlẹ́rìí.”
6 Nígbà náà ni Sámúẹ́lì wí fún àwọn ènìyàn náà pé, “Olúwa ni ó yan Mósè àti Árónì àti ti ó mú àwọn baba ńlá yín gòkè wá láti Éjíbítì.
7 Nísinsin yìí, ẹ dúró níbi, nítorí èmi ń lọ láti bá a yín sọ̀rọ̀ níwájú Olúwa ní ti gbogbo ìṣe òdodo rẹ̀ tí ó ti ṣe fún un yín àti fún àwọn baba yín.