4 Wọ́n sì dáhùn wí pé, “Ìwọ kò rẹ́ wa jẹ tàbí pọ́n wa lójú rí, ìwọ kò sì gba ohunkóhun lọ́wọ́ ẹnìkankan.”
5 Samúẹ́lì sì wí fún wọn pé, “Olúwa ni ẹlẹ́rìí sí i yín, àti ẹni àmì òróró rẹ̀ ni ẹlẹ́rìí lónìí pé, ẹ̀yin kò rí ohunkóhun lọ́wọ́ mi.”Wọ́n sì sọ wí pé, “Òun ni ẹlẹ́rìí.”
6 Nígbà náà ni Sámúẹ́lì wí fún àwọn ènìyàn náà pé, “Olúwa ni ó yan Mósè àti Árónì àti ti ó mú àwọn baba ńlá yín gòkè wá láti Éjíbítì.
7 Nísinsin yìí, ẹ dúró níbi, nítorí èmi ń lọ láti bá a yín sọ̀rọ̀ níwájú Olúwa ní ti gbogbo ìṣe òdodo rẹ̀ tí ó ti ṣe fún un yín àti fún àwọn baba yín.
8 “Lẹ́yìn ìgbà tí Jákọ́bù wọ Éjíbítì, wọ́n ké pe Olúwa fún ìrànlọ́wọ́, Olúwa sì rán Mósè àti Árónì, tí wọ́n mú àwọn baba ńlá yín jáde láti Éjíbítì láti mú wọn jókòó níbí yìí.
9 “Ṣùgbọ́n wọ́n gbàgbé Olúwa Ọlọ́run wọn; bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì tà wọ́n sí ọwọ́ àwọn Sísérà, olórí ogun Hásórì, àti sí ọwọ́ àwọn Fílístínì àti sí ọwọ́ ọba Móábù, tí ó bá wọn jà.
10 Wọ́n kégbe pe Olúwa, wọ́n sì wí pé, ‘Àwa ti ṣẹ̀; a ti kọ Olúwa sílẹ̀, a sì ti sin Báálì, àti Ásítarótì. Ṣùgbọ́n nísinsìn yìí gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa, àwa yóò sì sìn ọ́.’