1 Ṣọ́ọ̀lù sì jẹ́ ọmọ ọgbọ̀n ọdún nígbà tí ó jọba, ó sì jọba lórí Ísírẹ́lì ní ọdún méjìlélógójì.
2 Ṣọ́ọ̀lù yan ẹgbẹ̀ẹ́dógún (3000) ọkùnrin ní Ísírẹ́lì, ẹgbẹ̀rún méjì (2000) sì wà lọ́dọ̀ rẹ̀ ní Míkimásì àti ní ìlú òkè Bẹ́tẹ́lì ẹgbẹ̀rún kan (1000) sì wà lọ́dọ̀ Jónátanì ní Gíbéà ti Bẹ́ńjámínì. Àwọn ọkùnrin tókù ni ó rán padà sí ilé e wọn.
3 Jónátánì sì kọlu ẹgbẹ́ ogun àwọn Fílístínì ní Gébà, Fílístínì sì gbọ́ èyí. Nígbà náà ni Ṣọ́ọ̀lù fọn ìpè yí gbogbo ilẹ̀ náà ká, ó sì wí pé, “Jẹ́ kí àwọn Hébérù gbọ́!”
4 Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo Ísírẹ́lì sì gbọ́ ìròyìn pé, “Ṣọ́ọ̀lù ti kọlu ẹgbẹ́ ogun àwọn Fílístínì, Ísírẹ́lì sì di òórùn búburú fún àwọn Fílístínì.” Àwọn ènìyàn náà sì péjọ láti dara pọ̀ mọ́ Ṣọ́ọ̀lù ní Gílígálì.