1 Sámúẹ́lì 13:1-7 BMY

1 Ṣọ́ọ̀lù sì jẹ́ ọmọ ọgbọ̀n ọdún nígbà tí ó jọba, ó sì jọba lórí Ísírẹ́lì ní ọdún méjìlélógójì.

2 Ṣọ́ọ̀lù yan ẹgbẹ̀ẹ́dógún (3000) ọkùnrin ní Ísírẹ́lì, ẹgbẹ̀rún méjì (2000) sì wà lọ́dọ̀ rẹ̀ ní Míkimásì àti ní ìlú òkè Bẹ́tẹ́lì ẹgbẹ̀rún kan (1000) sì wà lọ́dọ̀ Jónátanì ní Gíbéà ti Bẹ́ńjámínì. Àwọn ọkùnrin tókù ni ó rán padà sí ilé e wọn.

3 Jónátánì sì kọlu ẹgbẹ́ ogun àwọn Fílístínì ní Gébà, Fílístínì sì gbọ́ èyí. Nígbà náà ni Ṣọ́ọ̀lù fọn ìpè yí gbogbo ilẹ̀ náà ká, ó sì wí pé, “Jẹ́ kí àwọn Hébérù gbọ́!”

4 Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo Ísírẹ́lì sì gbọ́ ìròyìn pé, “Ṣọ́ọ̀lù ti kọlu ẹgbẹ́ ogun àwọn Fílístínì, Ísírẹ́lì sì di òórùn búburú fún àwọn Fílístínì.” Àwọn ènìyàn náà sì péjọ láti dara pọ̀ mọ́ Ṣọ́ọ̀lù ní Gílígálì.

5 Àwọn Fílístínì kó ara wọn jọ pọ̀ láti bá Ísírẹ́lì jà, pẹ̀lú ẹgbàá-mẹ́ẹ̀dógún kẹ̀kẹ́, (3000) ẹgbẹ̀ta (6000) ọkùnrin ẹlẹ́ṣin, àwọn ológun sì pọ̀ bí yanrìn etí òkun. Wọ́n sì gòkè lọ, wọ́n dó ní Míkímásì ní ìhà ilẹ̀ oòrùn Bẹti-Áfénì.

6 Nígbà tí àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì sì rí i pé àwọn wà nínú ìpọ́njú àti pé àwọn ológun wọn wà nínú ìhámọ́, wọ́n fara pamọ́ nínú ihò àti nínú igbó láàárin àpáta, nínú ọ̀fìn, àti nínú kàǹga gbígbẹ.

7 Àwọn Hébérù mìíràn tilẹ̀ kọjá a Jọ́dánì sí ilẹ̀ Gádì àti Gílíádì.Ṣọ́ọ̀lù wà ní Gílígálì ṣíbẹ̀, gbogbo àwọn ọ̀wọ́-ogun tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ sì ń wárìrì fún ìbẹ̀rù.