15 Pẹ̀lú, kí wọn tó sun ọ̀rá náà, ìráńṣẹ́ àlùfáà á dé, á sì wí fún ọkùnrin tí ó ń ṣe ìrúbọ pé, “Fi ẹran fún mi láti sun fún àlùfàá; nítorí tí kì yóò gba ẹran sísè lọ́wọ́ rẹ, bí kò se tútù.”
16 Bí ọkùnrin náà bá sì wí fún un pé, “Jẹ́ kí wọn ó sun ọ̀rá náà nísinsin yìí, kí o sì mú iyekíye tí ọkàn rẹ̀ bá fẹ́;” nígbà náà ni yóò dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, ṣùgbọ́n kí ìwọ ó fi í fún mi nísinsin yìí, bí kó ṣe bẹ́ẹ̀, èmi ó fi agbára gbà á.”
17 Ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ọ̀dọ́mọkùrin náà sì tóbi gidigidi níwájú Olúwa: nítorí tí ènìyàn kórìíra ẹbọ Olúwa.
18 Ṣùgbọ́n Sámúẹ́lì ń ṣe ìráńṣẹ́ níwájú Olúwa, ọmọdé, ti a wọ̀ ní éfódì ọ̀gbọ̀.
19 Pẹ̀lúpẹ̀lú, ìyá rẹ̀ máa ń dá aṣọ ìlekè péńpé fún un, a sì máa mu wá fún un lọdọọdún, nígbà tí ó bá bá ọkọ rẹ̀ gòkè wá láti ṣe ìrúbọ ọdún.
20 Élì súre fún Elikánà àti aya rẹ̀ pé, “Kí Olúwa fún ọ ní irú-ọmọ láti ara obìnrin yìí wá, nítorí ẹ̀bùn tí ó béèrè tí ó sì tún fún Olúwa.” Wọ́n sì lọ sí ilé wọn.
21 Olúwa si bojú wo Hánà, ó sì lóyún, ó bí ọmọkùnrin mẹ́ta àti ọmọbìnrin méjì. Sámúẹ́lì ọmọ náà sì ń dàgbà níwájú Olúwa.