22 Élì sì di arúgbó gidigidi, ó sì gbọ́ gbogbo èyí ti àwọn ọmọ rẹ̀ ṣe sí gbogbo Ísírẹ́lì; àti bi wọ́n ti máa ń bá àwọn obìnrin sùn, tí wọ́n máa ń péjọ ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ àjọ.
23 Ó sì wí fún wọn pé, kí ni ó ti ri “Èétirí tí èmi fi ń gbọ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ sí yín? Nítorí tí èmi ń gbọ́ iṣẹ́ búburú yín láti ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn.
24 Bẹ́ẹ̀ kọ́ ẹ̀yin ọmọ mi, nítorí kì ṣe ìròyìn rere èmi gbọ́; ẹyin mú ènìyàn Ọlọ́run dẹ́ṣẹ̀.
25 Bí ẹnìkan bá ṣẹ̀ sí ẹnìkejì, onídàájọ́ yóò ṣe ìdájọ́ rẹ̀: ṣùgbọ́n bí ẹnìkan bá ṣẹ̀ sí Olúwa, tani yóò bẹ̀bẹ̀ fún un?” Wọn kò sì fi etí sí ohùn baba wọn, nítorí tí Olúwa ń fẹ́ pa wọ́n.
26 Ọmọ náà Sámúẹ́lì ń dàgbà, ó sì rí ojúrere lọ́dọ̀ Olúwa, àti ènìyàn pẹ̀lú.
27 Ènìyàn Ọlọ́run kan tọ Élì wá, ó sì wí fún un pé, “Báyìí ni Olúwa wí, ‘Èmi fi ara mi hàn ní gbangba fún ilé baba rẹ̀, nígbà tí wọ́n ń bẹ nínú ilé Fáráò.
28 Èmi Éjíbítì sì yàn án kúrò láàrin gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì láti jẹ́ àlùfáà mi, láti rúbọ lórí pẹpẹ mi, lati fi tùràrí jóná, láti wọ éfódì níwájú mi, èmi sì fi gbogbo ẹbọ tí ọmọ Ísírẹ́lì máa ń fi iná sun fún ìdílé baba rẹ̀.