23 Ó sì wí fún wọn pé, kí ni ó ti ri “Èétirí tí èmi fi ń gbọ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ sí yín? Nítorí tí èmi ń gbọ́ iṣẹ́ búburú yín láti ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn.
24 Bẹ́ẹ̀ kọ́ ẹ̀yin ọmọ mi, nítorí kì ṣe ìròyìn rere èmi gbọ́; ẹyin mú ènìyàn Ọlọ́run dẹ́ṣẹ̀.
25 Bí ẹnìkan bá ṣẹ̀ sí ẹnìkejì, onídàájọ́ yóò ṣe ìdájọ́ rẹ̀: ṣùgbọ́n bí ẹnìkan bá ṣẹ̀ sí Olúwa, tani yóò bẹ̀bẹ̀ fún un?” Wọn kò sì fi etí sí ohùn baba wọn, nítorí tí Olúwa ń fẹ́ pa wọ́n.
26 Ọmọ náà Sámúẹ́lì ń dàgbà, ó sì rí ojúrere lọ́dọ̀ Olúwa, àti ènìyàn pẹ̀lú.
27 Ènìyàn Ọlọ́run kan tọ Élì wá, ó sì wí fún un pé, “Báyìí ni Olúwa wí, ‘Èmi fi ara mi hàn ní gbangba fún ilé baba rẹ̀, nígbà tí wọ́n ń bẹ nínú ilé Fáráò.
28 Èmi Éjíbítì sì yàn án kúrò láàrin gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì láti jẹ́ àlùfáà mi, láti rúbọ lórí pẹpẹ mi, lati fi tùràrí jóná, láti wọ éfódì níwájú mi, èmi sì fi gbogbo ẹbọ tí ọmọ Ísírẹ́lì máa ń fi iná sun fún ìdílé baba rẹ̀.
29 Èé ha ṣe tí ẹ̀yin fi tàpá sí ẹbọ àti ọrẹ mi, tí mo páṣẹ ní ibùjókòó mi: ìwọ sì bu ọlá fún àwọn ọmọ rẹ jú mí lọ, tí ẹ sì fi gbogbo àṣàyàn ẹbọ Ísírẹ́lì àwọn ènìyàn mi mú ara yín sanra.’