1 Dáfídì sì wí ní ọkàn ara rẹ̀ pé, “Ǹjẹ́ ni ìjọ kan ni èmi yóò ti ọwọ́ Ṣọ́ọ̀lù ṣègbé, kò sì sí ohun tí ó yẹ mí jù kí èmi yára sá àsálà lọ sórí ilẹ̀ àwọn Fílístínì: yóò sú Ṣọ́ọ̀lù láti máa tún wa mi kiri ní gbogbo agbégbé Ísírẹ́lì: èmi a sì bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀.”
2 Dáfídì sì dìde, ó sì rékọjá, òun pẹ̀lú ẹgbẹ̀ta ọmọkùnrin tí o ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ sí Ákíṣì, ọmọ Máókì, ọba Gátì.
3 Dáfídì sì bá Ákíṣì jókòó ní Gátì, òun, àti àwọn ọmọkùnrin rẹ, olúkúlùkù wọn pẹ̀lú ará ilé rẹ̀; Dáfídì pẹ̀lú àwọn aya rẹ̀ méjèèjì, Áhínóámù ara Jésréélì, àti Ábígáílì ará Kámẹ́lì aya Nábálì.
4 A sì sọ fún Ṣọ́ọ̀lù pé, Dáfídì sá lọ si Gátì: òun kò sì tún wá á kiri mọ́.