16 Sámúẹ́lì sì wí pé, “Ó ti ṣe ń bi mí léèrè nígbà tí ó jẹ́ pé, Olúwa ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀, o sì di ọ̀tá rẹ̀.
17 Olúwa sì ṣe fún ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti ti ipa ọwọ́ mi sọ: Olúwa sì yá ìjọba náà kúrò ní ọwọ́ rẹ̀, ó sì fi fún aládùúgbò rẹ́, àní Dáfídì.
18 Nítorí pé ìwọ kò gbọ́ ohùn Olúwa ìwọ kò sì ṣe iṣẹ́ ìbínú rẹ̀ sí Ámálékì nítorí náà ni Olúwa sì ṣe nǹkan yìí sí ọ lónìí yìí.
19 Olúwa yóò sì fi Ísírẹ́lì pẹ̀lú ìwọ lé àwọn Fílístínì lọ́wọ́: ní ọ̀la ni ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin yóò pẹ̀lú mi: Olúwa yóò sì fi ogun Ísírẹ́lì lé àwọn Fílístínì lọ́wọ́.”
20 Lojúkan náà ni Ṣọ́ọ̀lù ṣubú lulẹ̀ gbalaja ní bí ó ṣe gùn tó, ẹ̀rù sì bà á gidigidi nítorí ọ̀rọ̀ Sámúẹ́lì; agbára kò sí fún un; nítorí pé kò jẹun ní ọjọ́ náà t'ọ̀sán t'òru.
21 Obìnrin náà sì tọ Ṣọ́ọ̀lù wá, ó sì rí i pé ó wà nínú ìbànújẹ́ púpọ̀, ó sì wí fún un pé, “Wò ó, ìránṣẹ́bìnrin rẹ́ ti gbọ́ ohun rẹ̀, èmi sì ti fi ẹ̀mi mi sí ọwọ́ mi, èmi sì ti gbọ́ ọ̀rọ̀ ti ìwọ sọ fún mi.
22 Ǹjẹ́, nísinsìnyìí èmi bẹ̀ ọ́, gbọ́ ohùn ìránṣẹ́bìnrin rẹ, èmi yóò sì fi oúnjẹ díẹ̀ ṣíwájú rẹ̀; sì jẹun, ìwọ yóò sì lágbára, nígbà tí ìwọ bá ń lọ lọ́nà.”