1 Sámúẹ́lì 29:5-11 BMY

5 Ṣé èyí ni Dáfídì ti wọn torí rẹ̀ gberin ara wọn nínú ìjọ wí pé,“ ‘Ṣọ́ọ̀lù pa ẹgbẹgbẹrun rẹ̀,Dáfídì si pa ẹgbẹgbàárun tirẹ́.’ ”

6 Ákíṣì sì pe Dáfídì, ó sì wí fún un pé, “Bí Olúwa ti ń bẹ láàyè, ìwọ jẹ́ ólóòótọ́ àti ẹni ìwà rere lójú mi, ní àlọ rẹ àti ààbọ̀ rẹ pẹ̀lú mi ní ogun: nítorí pé èmi ko tìí ri búburú kan lọ́wọ́ rẹ́ láti ọjọ́ ti ìwọ ti tọ̀ mí wá, títí o fi dì òní yìí ṣùgbọ́n lójú àwọn ìjòyè, ìwọ kò ṣe ẹni tí ó tọ́.

7 Ǹjẹ́ yípadà kí o sì máa lọ ní àlàáfíà, kí ìwọ má ṣe bà àwọn Fílístínì nínú jẹ́.”

8 Dáfídì sì wí fún Ákíṣì pé, “Kín ni èmi ṣe? Kín ni ìwọ sì rí lọ́wọ́ ìránṣẹ́ rẹ láti ọjọ́ ti èmi ti ń gbé níwájú rẹ títí di òní yìí, tí èmi kì yóò fi lọ bá àwọn ọ̀ta ọba jà.”

9 Ákíṣì sì dáhùn, ó sì wí fún Dáfídì pé, “Èmi mọ̀ pé ìwọ ṣe ẹni-rere lójú mi, bi ańgẹ́lì Ọlọ́run; ṣùgbọ́n àwọn ìjòyè Fílístínì wí pé, Òun kì yóò bá wa lọ sí ogun.

10 Ǹjẹ́, nísinsin yìí dìde ní òwúrọ pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ olúwa rẹ tí ó bá ọ wá: ki ẹ si dìde ní òwúrọ̀ nígbà tí ilẹ̀ bá mọ́ kí ẹ sì máa lọ.”

11 Dáfídì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì dìde ní òwúrọ̀ láti padà lọ sí ilẹ̀ àwọn Fílístínì. Àwọn Fílístínì sì gòkè lọ sí Jésírélì.