12 Nígbà náà; àwọn màlúù lọ tààrà sí ìhà Béti-Ṣémésì, wọ́n ń lọ tààrà, wọ́n sì ń dún bí wọ́n ti ń lọ. Wọn kò yà sí ọ̀tún tàbí yà sí òsì. Àwọn aláṣẹ Fílístínì tẹ̀lé wọn títí dé ibodè Bẹti-Sémésì.
13 Nísinsìn yìí, àwọn ará Bẹti-Sémésì ń kórè jéró wọn ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, nígbà tí wọ́n wo òkè tí wọ́n sì rí àpótí ẹ̀rí Olúwa, wọ́n yọ̀ níwájú rẹ̀.
14 Kẹ̀kẹ̀ ẹrù wá sí pápá Jóṣúà ti Bẹti-Sémésì, níbẹ̀ ni ó ti dúró ní ẹ̀bá àpáta ńlá kan. Àwọn ènìyàn gé igi ara kẹ̀kẹ́ ẹrù sí wẹ́wẹ́ wọ́n sì fi àwọn màlúù náà rúbọ sísun sí Olúwa.
15 Àwọn ará Léfì gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa wá sí ìṣàlẹ̀ pẹ̀lú àpótí tí ohun èlò wúrà wà níbẹ̀, wọ́n sì gbé wọn ka orí àpáta ńlá náà. Ní ọjọ́ náà, àwọn ará Bẹti-Sémésì rú ẹbọ sísun, wọ́n sì ṣe ìrúbọ sí Olúwa.
16 Àwọn aláṣẹ Fílístínì márààrún rí gbogbo èyí, wọ́n sì padà ní ọjọ́ náà sí Ékírónì.
17 Èyí ni kókó wúrà tí àwọn Fílístínì fún Olúwa gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀bi ọ̀kọ̀ọ̀kan fún Ásídódù, ọ̀kan ti Gásà, ọ̀kan ti Ásíkélónì, ọ̀kan ti Gátì, ọ̀kan ti Ékírónì.
18 Góòlù eku-ẹ̀lírí jẹ́ iye ìlú tí àwọn aláṣẹ Fílístínì márààrún ti wá, ìlú olodi pẹ̀lú ìlétò wọn. Àpáta ńlá náà, lórí èyí tí a gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa lé jẹ́ ẹ̀rí títí di òní ní oko Jóṣúà ará Bẹti-Sémésì.