6 Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n wí pé, “Fún wa ní ọba tí yóò darí wa” Èyí kò tẹ́ Sámúẹ́lì lọ́rùn, ó sì gbàdúrà sí Olúwa.
7 Olúwa sì sọ fún un pé: “Tẹ́tí sí gbogbo ohun tí àwọn ènìyàn ń sọ fún ọ; kì í ṣe ìwọ ni wọ́n kọ̀, ṣùgbọ́n Èmi ni wọ́n kọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba wọn.
8 Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe ní ọjọ́ tí mo mú wọn jáde wá láti Éjíbítì títí di ọjọ́ òní, wọ́n kọ̀ mí sílẹ̀, wọ́n sì ń sin Ọlọ́run mìíràn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń ṣe sí ọ.
9 Nísinsìn yìí, gbọ́ ti wọn; ṣùgbọ́n kìlọ̀ fún wọn dáadáa, kí o sì jẹ kí wọ́n mọ irú ohun tí ọba tí yóò jẹ́ lórí wọn yóò ṣe.”
10 Sámúẹ́lì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ Olúwa sí àwọn ọmọ ènìyàn tí ó ń béèrè fún ọba lọ́wọ́ rẹ̀.
11 Ó wí pé, “Èyí ni ohun tí ọba tí yóò jẹ lórí yín yóò ṣe. Yóò kó àwọn ọmọkùnrin yín, yóò sì mú wọn ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ àti fún ẹlẹ́sin rẹ, wọn yóò sì máa sáré níwájú kẹ̀kẹ́ rẹ̀.
12 Yóò yan díẹ̀ láti jẹ́ olórí ẹgbẹ̀rún àti olórí àádọ́ta àti àwọn mìíràn. Yóò yan wọ́n láti máa tulẹ̀ oko rẹ̀ àti láti máa kórè rẹ̀ àti àwọn mìíràn láti máa ṣe ohun èlò ogun àti ohun èlò kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀.