1 Àwọn òwe ti Sólómónì, ọmọ Dáfídì, ọba Ísírẹ́lì.
2 Láti le ní ọgbọ́n àti ẹ̀kọ́Láti ní òye àwọn ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀
3 Láti ní ẹ̀kọ́ àti gbé ìgbé ayé ìkíyèsára,láti ṣe ohun tí ó tọ́, àti òdodo tí ó sì dára
4 láti fún onírẹ̀lẹ̀ ní ìkíyèsáraìmọ̀ àti ìṣọ́ra fún àwọn èwe
5 Jẹ́ kí Ọlọgbọ́n tẹ́tí kí ó sì ní ìmọ̀ kún ìmọ̀,sì jẹ́ kí ẹni òye gba ìtọ́sọ́nà
6 láti mọ ìtumọ̀ òwe àti ìtàn-dòwe, (àlọ́ onítàn)àwọn ọ̀rọ̀ àti àlọ́ àwọn Ọlọgbọ́n.
7 Ìbẹ̀rù Olúwa ni ìbẹ̀rẹ̀ ìmọ̀,ṣùgbọ́n aláìgbọ́n kẹ́gàn ọgbọ́n àti ẹ̀kọ́.