10 Ọmọ mi, bí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ bá ń tàn ọ́,má ṣe gbà fún wọn.
11 Bí wọn bá wí pé, “Tẹ̀lé wa kálọ;jẹ́ ká ba ní ibùba fún ẹ̀jẹ̀ ẹnìkan,jẹ́ ká dá àwọn aláìlera kan lọ́nà;
12 Jẹ́ ká gbé wọn mì láàyè, bí ibojì òkú,àti lódindi, bí àwọn tí ń sọ̀kalẹ̀ lọ sínú kòtò;
13 A ó rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan tó níye lóría ó sì fi ìkógún kún inú ilé wa;
14 Dara pọ̀ mọ́ wa,a ó sì jọ powó sínú àpò kan náà”
15 Ọmọ mi, má ṣe bá wọn lọ,má ṣe rìn ní ojú ọ̀nà wọn;
16 Nítorí ẹsẹ̀ wọn ń sáré sí ẹ̀ṣẹ̀,wọ́n yára láti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀.