15 Ọmọ mi, má ṣe bá wọn lọ,má ṣe rìn ní ojú ọ̀nà wọn;
16 Nítorí ẹsẹ̀ wọn ń sáré sí ẹ̀ṣẹ̀,wọ́n yára láti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀.
17 Wàhálà asán ni kí ènìyàn máa dẹ okùn de ẹyẹ,ní ìṣojú u gbó ẹyẹ!
18 Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ń lúgọ fún ẹ̀jẹ̀ ara wọn.Ara wọn ni wọ́n ń dá lóhùn
19 Báyìí ni ìgbẹ̀yìn gbogbo àwọn tí ń wá èrè àìtọ́;yóò mú ẹ̀mí gbogbo ẹni tí ó rí i lọÌkìlọ̀ láti má ṣe kọ ọgbọ́n sílẹ̀
20 Ọgbọ́n kígbe sókè ní pópóó gbé ohùn rẹ̀ sókè láàrin ọjà;
21 Láàrin ọjà ni ó ti kígbe jádeNí ibodè ìlú ni ó ti sọ̀rọ̀ ọ rẹ̀: