8 Tẹ́tí, ìwọ ọmọ mi sí ẹ̀kọ́ baba rẹmá ṣe kọ ẹ̀kọ́ màmá ọ̀ rẹ sílẹ̀
9 Wọn yóò jẹ́ òdòdó ẹ̀yẹ olóòrùn dídùn lórí rẹàti ọ̀ṣọ́ tí ó dára yí ọrùn rẹ ká.
10 Ọmọ mi, bí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ bá ń tàn ọ́,má ṣe gbà fún wọn.
11 Bí wọn bá wí pé, “Tẹ̀lé wa kálọ;jẹ́ ká ba ní ibùba fún ẹ̀jẹ̀ ẹnìkan,jẹ́ ká dá àwọn aláìlera kan lọ́nà;
12 Jẹ́ ká gbé wọn mì láàyè, bí ibojì òkú,àti lódindi, bí àwọn tí ń sọ̀kalẹ̀ lọ sínú kòtò;
13 A ó rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan tó níye lóría ó sì fi ìkógún kún inú ilé wa;
14 Dara pọ̀ mọ́ wa,a ó sì jọ powó sínú àpò kan náà”