10 Nígbà tí Olódodo ń gbèrú, ìlú a yọ̀nígbà tí ènìyàn búburú parun, ariwo ayọ̀ gba ìlú kan.
11 Nípaṣẹ̀ ìbùkún, Olódodo a gbé ìlú ga:ṣùgbọ́n nípaṣẹ̀ ẹnu ènìyàn búburú, a pa ìlú run.
12 Ẹni tí kò gbọ́n fojú kékeré wo aládùúgbò rẹ̀ṣùgbọ́n ẹni tí ó ní òye pa ẹnu rẹ̀ mọ́.
13 Olófòófó tú àsírí ìkọ̀kọ̀ṣùgbọ́n ẹni tó ṣe é gbẹ́kẹ̀lé a pa àsírí mọ́.
14 Nítorí àìní ìtọ́sọ́nà orílẹ̀ èdè ṣubúṣùgbọ́n nípaṣẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ olùbádámọ̀ràn ìṣẹ́gun dájú.
15 Ẹni tí ó ṣe onídùúró fún ẹlòmíràn yóò jìyà dájúdájú,ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó kọ̀ láti ṣe onídùúró yóò wà láì léwu.
16 Obìnrin oníwà rere gba ìyìnṣùgbọ́n alágbára aláìbìkítà ènìyàn gba ọrọ̀ nìkan.