16 Obìnrin oníwà rere gba ìyìnṣùgbọ́n alágbára aláìbìkítà ènìyàn gba ọrọ̀ nìkan.
17 Ènìyàn rere ń ṣe ara rẹ̀ lóoreṣùgbọ́n ènìyàn ìkà ń mú ìyọnu wá sórí ara rẹ̀.
18 Ènìyàn búburú gba èrè ìtànjẹṣùgbọ́n ẹni tó fúrúgbìn òdodo yóò gba èrè tó dájú.
19 Olódodo tòótọ́ rí ìyèṣùgbọ́n ẹni tí ń lépa ibi lé e sí ibi ikú ara rẹ̀.
20 Olúwa kórìíra àwọn ènìyàn ọlọ́kàn búburúṣùgbọ́n ó ní inú dídùn sí àwọn tí ọ̀nà wọn kò lábùkù.
21 Mọ èyí dájú pé: ènìyàn búburú kì yóò lọ láì jìyà,ṣùgbọ́n àwọn Olódodo yóò lọ láì jìyà.
22 Bí òrùka wúrà ní imú ẹlẹ́dẹ̀ni arẹwà obìnrin tí kò lọ́gbọ́n.