22 Bí òrùka wúrà ní imú ẹlẹ́dẹ̀ni arẹwà obìnrin tí kò lọ́gbọ́n.
23 Ìfẹ́ inú Olódodo yóò yọrí sí ohun rereṣùgbọ́n ìrètí ènìyàn búburú yóò yọrí sí ìbínú.
24 Ènìyàn kan ń fún ni lọ́fẹ̀ ẹ́, síbẹ̀ ó ń ní sí i;òmíràn ń háwọ́ ju bí ó ti yẹ ṣùgbọ́n ó di aláìní.
25 Ẹni tí ń ṣoore yóò máa gbèrú sí i;ẹni tí ó tu ẹlòmíràn lára yóò ní ìtura.
26 Àwọn ènìyàn a ṣépè lé ènìyàn tí ń kó oúnjẹ pamọ́ṣùgbọ́n ìbùkún a máa wá sórí ẹni tí ó ṣetán láti tà.
27 Ẹni tí ń lépa ohun rere yóò rí ohun rereṣùgbọ́n ibi yóò dé bá ẹni tí ń lépa ibi.
28 Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ rẹ̀ yóò ṣubú;ṣùgbọ́n Olódodo yóò gbilẹ̀ bí i koríko tútù.