14 A ó san án lẹ́kùnrẹ́rẹ́ fún aláìgbàgbọ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ̀Ènìyàn rere yóò sì gba èrè fún tirẹ̀.
15 Òpè ènìyàn gba ohun gbogbo gbọ́ṣùgbọ́n Olóye ènìyàn ronú lórí àwọn ìgbéṣẹ̀ rẹ̀.
16 Ọlọgbọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run ó sì kórìíra ibiṣùgbọ́n aláìgbọ́n jẹ́ alágídí àti aláìṣọ́ra.
17 Ẹni tí ó máa ń tètè bínú máa ń hùwà aṣiwèrè,a sì kórìíra eléte ènìyàn:
18 Òpè jogún ìwà òmùgọ̀ṣùgbọ́n a dé ọlọgbọ́n ní adé ìmọ̀.
19 Ènìyàn ìkà yóò tẹríba níwájú àwọn ènìyàn rereàti ènìyàn búburú níbi ìlẹ̀kùn àwọn olódodo.
20 Kódà àwọn aládùúgbò o talákà kò fẹ́ràn rẹ̀ṣùgbọ́n, Ọlọ́rọ̀ ní ọ̀rẹ́ púpọ̀.